CGS Number
494
CGS Lyrics
Ẹsẹ 1
Ha! ẹgbẹ mi, ẹ w’ asia
Bi ti nfẹ lẹlẹ!
Ogun Jesu fẹrẹ de na,
A fẹrẹ ṣẹgun!

Chorus
“D’ odi mu, emi fẹrẹ de,”
Bẹẹni Jesu nwi,
Ran ‘dahun pada s’ Ọrun pe,
Awa o dimu.

Ẹsẹ 2
Wo ọpọ ogun ti mbọ wa,
Eṣu nko wọn bọ;
Awọn alagbara nṣubu,
A fẹ dãmu tan!

Chorus
“D’ odi mu, emi fẹrẹ de,”
Bẹẹni Jesu nwi,
Ran ‘dahun pada s’ Ọrun pe,
Awa o dimu.

Ẹsẹ 3
Wo asia Jesu ti nfẹ,
Gbọ ohun ipe;
A o ṣẹgun gbogbo ọta
Ni orukọ Rẹ.

Chorus
“D’ odi mu, emi fẹrẹ de,”
Bẹẹni Jesu nwi,
Ran ‘dahun pada s’ Ọrun pe,
Awa o dimu.

Ẹsẹ 4
Ogun ngbona girigiri,
Iranwọ wa mbọ;
Balogun wa mbọ wa tete,
Ẹgbẹ, tujuka!

Chorus
“D’ odi mu, emi fẹrẹ de,”
Bẹẹni Jesu nwi,
Ran ‘dahun pada s’ Ọrun pe,
Awa o dimu.

Yoruba