CGS Number
95
CGS Lyrics
Ẹsẹ 1
‘Bukun wakati na ti to
Jesu, ‘gba t’ a sunmọ Ọ,
Lati gbọ ọrọ ‘yebiye!
Ti nti ẹnu Rẹ jade!

Ẹsẹ 2
Pẹlu wa loni, bukun wa,
K’ a má j’ olugbọ lasan
Tẹ õtọ Rẹ mọ wa l’ aya
Ti mbẹ n’ nu ọrọ iye.

Ẹsẹ 3
Wò wa b’ a ti nwa igbala
Ti a joko l’ ẹṣẹ Rẹ
A nreti ni iparọrọ
Lati gb’ ohun didun Rẹ.

Ẹsẹ 4
La wa n’ iyè, k’ O si tọ wa,
L’ alafia lọna ọrun;
F’ atupa õtọ ṣaju wa,
Ki a má ba ṣina lọ.

Ẹsẹ 5
Ṣe wa l’ ẹni tutu, pẹlẹẹ
K’ a mã f’ igboya ṣ’ õtọ:
L’ õkùn lọ, k’ a má ba kọsẹ
Kò s’ ewu l’ ojumọmọ.

Ẹsẹ 6
F’ imọlẹ, ifẹ, agbára
Fun ọrọ Rẹ lat’ oke
K’ o mã ṣiṣẹ b’ iwukara
Ni inu wa titi lọ.

Ẹsẹ 7
Ràn wa lọwọ k’ a le jẹri
Si otitọ t’ a dimu;
K’ a si jẹ k’ awọn ẹlomi
Tọ adun õtọ na wò.

Yoruba