Joṣua 7:1-25; 8:1-35

Lesson 52 - Elementary

Memory Verse
: “Ifẹ owo ni gbòngbo ohun buburu gbogbo”(1 Timoteu 6:10)
Notes
Joṣua kilọ fun awọn eniyan pe, wọn ko gbọdọ mu ohunkohun afi wura, fadaka ati awọn ago idẹ, ati irin ti wọn le fi si ile Ọlọrun. Ọlọrun fé̩ wa, Oun a si sọ fun wa bi ewu bá wà niwaju. Awa yoo layọ bi a ba gbọran.

Lẹyin ti wọn gba Jẹriko, wọn ni lati tè̩ siwaju lati gba ilẹ miiran. Ilu naa kere ju Jẹriko. Ọmọ-ogun diẹ ni Joṣua mú lọ. Wọn gbagbọ pe Ọlọrun yoo wà pẹlu wọn yoo si ràn wọn lọwọ gẹgẹ bi O ti ṣe fun wọn ni Jẹriko. Inu Joṣua ati awọn ọmọ-ogun bajẹ, ẹnu si ya wọn pupọ nigba ti awọn ọmọ ogun wọn sá kuro niwaju awọn ọmọ-ogun kekere naa. Joṣua gbadura o si beere lọwọ Ọlọrun idi rè̩ ti kò fi ràn wọn lọwọ. Joṣua sọ pe oun ko le ṣe ohun kan afi bi Ọlọrun ba ran oun lọwọ. Joṣua mọ pe oun ko le lọ ninu agbara oun lai si iranlọwọ Ọlọrun. Ọrọ Ọlọrun sọ fun ni pe lai si Ọlọrun, a ko le ṣe ohun kan.

Ọlọrun sọ fun Joṣua pe ẹni kan ti ṣaigbọran si Ọlọrun, o ti jale, nitori naa ni Oun ko ṣe ran wọn lọwọ. Ọlọrun sọ fun Joṣua lati wá oluwarẹ ki o si jẹ ẹ niya. A mu awọn eniyan wá si iwaju Joṣua, Joṣua beere lọwọ rè̩ lati sọ ohun ti o ṣe. O ni lati jẹ pe Ọlọrun ni o fi han an. Akani jẹwọ pe oun ji wura diẹ, ẹwu kan, ati owó. Ẹṣẹ ni lati jale. Akani ko ro pe ẹnikẹni ri ohun ti oun ji, ṣugbọn Ọlọrun n ri ohun gbogbo ti a n ṣe. A ko le fara pamọ lọdọ Ọlọrun.

Joṣua gba ẹwu naa, wura ati owó lọwọ Akani o si dana sun wọn. Joṣua jẹ Akani ati awọn ara ile rè̩ niya. Ọlọrun fẹ fi hàn fun awọn eniyan pe ohun buburu ni lati ṣe aigbọran si Oun. Akani kó ara rè̩ ati awọn ara ile rè̩ sinu wahala ati ijiya. Nigba ti ẹni kan ba dẹṣẹ, o n fi apẹẹrẹ buburu lelẹ fun awọn miiran pẹlu. Nigba pupọ ni awọn obi maa n jiya nitori aigbọran awọn ọmọ wọn.

A ri i pe awọn eniyan wọnyii ṣẹgun nigba ti wọn gbọran si Ọlọrun, ṣugbọn a ṣẹgun wọn nigba ti wọn ṣaigbọran. Eyi kọ wa pe o dara lati ṣe ohun ti Ọlọrun fẹ ki a ṣe e nitori a fẹran Rè̩.

Questions
AWỌN IBEERE
  1. 1 Ki ni ṣe ti a ṣẹgun awọn Ọmọ Israeli? Joṣua 7:1

  2. 2 Bawo ni Joṣua ṣe mọ ẹni ti o dẹṣẹ?

  3. 3 Ki ni Joṣua sọ fun Akani? Joṣua 7:19

  4. 4 Ki Akani ṣe ti kò dara? Joṣua 7:21

  5. 5 Ki ni Ọlọrun sọ nipa ojukokoro?