Ẹksodu 5:1-35; 40:33-38

Lesson 36 - Elementary

Memory Verse
“Ninu ile Baba mi ọpọlọpọ ibugbe li o wà” (Johannu 14:2).
Notes

Nitori Mose wà pẹlu Ọlọrun fun igba pipẹ oju rè̩ n dán. O ni ohun pupọ lati sọ fun awọn eniyan naa ti Ọlọrun sọ fun un. Ọlọrun ti sọ fun un bi o ti le ran awọn eniyan naa lọwọ lati lè jé̩ oloootọ si Oun to bẹẹ ti Oun yoo maa ba wọn lọ ti Oun yoo si daabo bò wọn. Wọn ni lati ṣí kuro ni Sinai ki wọn maa lọ si ilẹ ti Ọlọrun n mu wọn lọ. Ọlọrun sọ fun Mose lati paṣẹ fun awọn eniyan naa lati pagọ kan fun Oun ninu eyi ti wọn o maa jọsin. Ko ni ṣoro fun wọn lati maa gbé e bi wọn ti n lọ ninu irin ajo wọn.

Mose sọ fun awọn eniyan lati mu ohun ti a o fi kọ agọ ati ohun ti yoo wà ninu rè̩ wá. Awọn eniyan naa mu wura, fadaka, igi, awọ ati ororo wá. Tọkantọkan ni wọn fi mu un wá. Iru ọrẹ bayii ni Ọlọrun n fé̩. Awọn ti wọn mọ aṣọ i hun hun aṣọ fun agọ naa. Ọlọrun ti pese awọn ti o mọ oriṣiriṣi iṣẹ i ṣe. Aṣọ isorọ elese aluko, alaro ododo ati ọgbọ olokun wiwẹ ti a sorọ mu ki agọ naa lẹwa pupọ. Awọn eniyan ti Mose yàn ni o n gbé agọ naa, gẹgẹ bi Ọlọrun ti paṣẹ fun wọn ni wọn ṣe n gbe e.

Pẹpẹ wà nibẹ nibi ti awọn eniyan n fi ọrẹ ẹbọ wọn si. Ọlọrun ṣeun pupọ fun wa O si fẹ ki a fi ohun kan fun Oun ni imoore fun ohun ti a ri gba, paapaa ju lọ Oun fẹ ki a fi ifẹ wa fun Oun. Ọlọrun sọ fun Mose lati yan awọn eniyan lati maa ṣe oriṣiriṣi iṣẹ ti wọn ni lati ṣe. Diẹ ninu wọn ni ẹwu ti wọn ni lati wọ fun iṣẹ iranṣẹ wọn. Ọlọrun sọ fun Mose bi yoo ti ṣe e. Mose si ṣe bi Ọlọrun ti sọ fun un. Inu Ọlọrun dùn nitori Mose gbọran. Ọlọrun ni Oun yoo sọ akoko ti wọn yoo gbé agọ naa kalẹ fun isin.

Nigba ti a pari agọ (Ile-Ijọsin) naa tán, Ọlọrun fi awọsanma bo o ninu eyi ti Oun paapaa wà. Mose ko le wọ inu rè̩ lọ nitori Ọlọrun wà nibẹ. Bi wọn ti n lọ ninu irin ajo wọn, awọsanma wà lori agọ lọsan, imọlẹ didan wà lori rè̩ loru ki gbogbo eniyan le ri i. Eyi fi hàn wọn pe Ọlọrun wà pẹlu wọn, O n ba wọn lọ. Ọlọrun ṣeto ohun gbogbo. Bi a ba ṣe ohunkohun ti Ọlọrun palaṣẹ lai jafara, awa yoo layọ, inu Baba wa ti o wà ni Ọrun yoo yọ si wa.

Questions
AWỌN IBEERE
  1. 1 Iru ọrẹ wo ni awọn Ọmọ Israeli mu wa fun Oluwa? Ẹksodu 35:29

  2. 2 Iru ọrẹ wo ni a ni lati mu wa fun Oluwa?

  3. 3 Bawo ni a ṣe ni lati ṣe nigba ti a ba wá si ile Ọlọrun?

  4. 4 Ki ni ṣẹlẹ nigba ti Mose pari iṣẹ naa? Ẹksodu 40:34

  5. 5 Bawo ni awọn Ọmọ Israeli ṣe n mọ akoko ti o yẹ ki wọn maa lọ ninu irin-ajo wọn? Ẹksodu 40:36