Gẹnẹsisi 1:31; 2:1-25; 3:1-24

Lesson 31 - Elementary

Memory Verse
“Lẹhin rè̩ a ko si da ohun kan ninu ti a da” (Johannu 1:3).
Notes

Ki ayé tabi ohunkohun ti o wà ninu rè̩ to wà ni Ọlọrun ti wà. O lagbara lati ṣe ohun gbogbo, ohunkohun ti O ba sọ yoo ṣẹ. Awọn miiran ko gbagbọ pe Ọlọrun ni o dá ayé, ṣugbọn awọn ti o gba Ọlọrun ati Bibeli gbọ mọ pe Ọlọrun ni o dá a ati pe Jesu ati Ẹni Mimọ wà pẹlu Rè̩ nigba ti O n dá a.

Ọlọrun wi pe, “ Ki imọlẹ ki o wà,” imọlẹ si wà. O pe imọlẹ ni “Ọsán” ati okunkun ni “Oru.” Ni ọjọ keji Ọlọrun dá awọsanma ati ikuuku ninu eyi ti omi ti n mu irugbin dagba wà. Ọlọrun gbá omi jọ pọ o di òkun nla, O si fi iyangbẹ ilẹ si àye ti rè̩. O mu ki koriko daradara hù lori ilẹ. Ọlọrun ṣe ibugbe daradara fun eniyan ṣugbọn è̩ṣẹ mú ègún wá sori rè̩.

Ọlọrun tun dá oorun lati ràn ni ọsán, oṣupa ati irawọ lati tan imọlẹ ni oru. Lẹyin ti Ọlọrun ti pari ibugbe eniyan, O fi ẹja sinu okun, O si fi ẹyẹ si oju ọrun. Ọlọrun si dá ọkunrin daradara kan sinu ayé daradara ti O ti dá. Erupẹ ilẹ ni O fi mọ eniyan, O si mi eemi iye si iho imu rè̩. Ohun gbogbo ti Ọlọrun dá, daradara ni. Eniyan nikan ni o le fẹran Ọlọrun ninu gbogbo ẹda ọwọ Rè̩. Ọlọrun sinmi ni ọjọ keje.

Ọlọrun gbin Ọgbà daradara kan fun Adamu ati awọn ti yoo wà pẹlu rè̩. Gbogbo igi ni wọn le jẹ eso rè̩ afi ọkan ṣoṣo ni wọn kò gbọdọ jẹ, wọn ko tilẹ gbọdọ fọwọ kan an. Ọlọrun ko fé̩ ki Adamu nikan wà, nigba ti Adamu sùn, Ọlọrun yọ ọkan ninu egungun iha rè̩ O fi dá obinrin ti i ṣe iyawo Adamu.

Ọpọlọpọ ẹranko ni o wà ninu Ọgbà. Adamu ni o sọ wọn lorukọ. Ki i ṣe gbogbo ejo ni o loro, ṣugbọn ejò kan wà ninu Ọgbà ti o buru lọpọlọpọ. Ni ọjọ kan o tọ Efa wá, o sọ fun un ki o jẹ eso ti Ọlọrun kọ fun wọn lati jẹ. Efa jẹ ẹ, o si fun ọkọ rè̩. Aṣiṣe nla ni Efa ṣe lati gbọ ti ejò dipo Ọlọrun. Tẹlẹ ri, Ọlọrun a maa tọ wọn wá ni irọlẹ, A si bá Adamu ati Efa sọrọ.

S̩ugbọn lẹyin ti wọn jẹ eso ni, ẹru ba wọn, wọn si fi ara pamọ. Ọlọrun beere lọwọ wọn bi wọn ti jẹ eso ni, wọn si bẹrẹ si i ṣe awawi. Nigba ti ẹlomiran bá dẹṣẹ, a fẹ lati ti ẹbi naa si ẹlomiran. Ọlọrun le wọn jade kuro ninu Ọgbà nitori aigbọran wọn, O si fi awọn angẹli ṣọ Ọgbà naa. Ohun ti o buru jù lọ ni Adamu ati Efa ṣe nigba ti wọn ṣaigbọran si Ọlọrun; eyi ni o fa è̩ṣẹ, aisàn ati ikú wá sinu ayé. Bi a ba ṣe ohun ti ko dara a n fi apẹẹrẹ buburu lelẹ ni.

Questions
AWỌN IBEERE
  1. 1 Njẹ Ọlọrun ti wà ni ipilẹṣẹ ki a to dá ayé? Gẹnẹsisi 1:1

  2. 2 Kn ni Ọlọrun kọ dá? Gẹnẹsisi 1:1

  3. 3 Ki ni Ọlọrun dá fun imọlẹ? Gẹnẹsisi 1:16

  4. 4 Ọjọ meloo ni Ọlọrun fi dá ohun gbogbo? Gẹnẹsisi 1:31

  5. 5 Nibo ni Ọlọrun fi eniyan si lẹyin ti o ti da a? Gẹnẹsisi 2:8