Gẹnẹsisi 1:1-31

Lesson 1 - Elementary

Memory Verse
“Nipasẹ rè̩ li a ti da ohun gbogbo” (Johannu 1:3).
Notes

Ọlọrun ni agbara lati ṣe ohun gbogbo. Bi O ba ti sọrọ yoo si ri bẹẹ. Nigba kan ri, okunkun bo ayé, Ọlọrun si wi pe: “Ki imọlẹ ki o wà,” imọlẹ si wà. Ọlọrun pe imọlẹ naa ni “Ọsán,” O si pe okunkun ni “Oru.”

Ni ọjọ keji, Ọlọrun dá awọsanma daradara ati ikuuku ti i maa fun awọn itanna ati igi ni omi ti o n mu wọn dagba, ki ounjẹ le wà fun eniyan ati ẹranko. Ọlọrun mu ki awọn omi wọjọ pọ o si di okun nla, O si fi iyangbẹ ilẹ si àyè rè̩. O paṣẹ fun okun pe ki o ma ṣe kọja ibi ti Oun fi i si, o si ri bẹẹ.

Lẹyin naa Ọlọrun fi koriko ati itanna daradara bo ori ilẹ. Ọlọrun dá ayé ti o lẹwa, paapaa ju lọ fun awọn ọkunrin ati obinrin ati ọdọmọkunrin ati ọdọmọbinrin ti Oun yoo dá.

Ni ọjọ kẹrin, Ọlọrun dá Oorun lati maa tan imọlẹ rẹ ni ọsán, oṣupa ati awọn irawọ lati tan imọlẹ wọn ni oru. Lẹyin ti Ọlọrun ti dá imọlẹ si ayé ti O si ti pese ibugbe fun eniyan, O dá awọn ẹja sinu okun. O si dá awọn ẹyẹ ti n fò loke.

Ọlọrun dá ayé daradara, O si dá ọkunrin daradara kan sinu rè̩. Ọlọrun wo ayé ti O dá , O si wi pe, “O dara.” Erupẹ ilẹ ni Ọlọrun fi mọ eniyan, O si mi eemi iye sinu rè̩.

Awọn oke, okun, itanna ati ohun gbogbo ti Ọlọrun dá fi hàn pe rere ni Ọlọrun, ṣugbọn ọmọ eniyan nikan ni o le fẹran Ọlọrun.

Gbogbo awọn ọdọmọkunrin, ọdọmọbinrin, ọkunrin ati obinrin ni gbogbo agbaye ni wọn fé̩ ki a fẹran wọn. Ọlọrun fé̩ ki awa naa fẹran Oun pẹlu. Eredi ti Ọlọrun fi dá iwọ ati emi ni yii, a ni lati fé̩ Ẹ ati lati sìn In.

Ohun ti a ni lati ṣe ni pe ki a fẹran Ọlọrun ki a si gbọran si I, Oun yoo si tọju wa, yoo si fun wa layọ. Nigba naa bi a ba n fẹ Ẹ, ti a si n gbọran si I nigba gbogbo, lọjọ kan, Oun yoo mú wa lọ si Ọrun lati maa ba A gbá lae ati laelae.

Questions
AWỌN IBEERE
  1. Bawo ni Ọlọrun ṣe dá ayé yii?
  2. Ki ni Ọlọrun dá ni ọjọ kin-in-ni?
  3. Darukọ awọn ohun ti Ọlọrun dá ki O tó dá eniyan.
  4. Ki ni Ọlọrun fi mọ eniyan?
  5. Ki ni ṣe ti O fi dá eniyan?